10/10/2022
Adisa agba omo Al'adin kikun, Orolu Adisa omo ar'owo d'eru ogun, apapalailai eruku lala Baba Ayomide, Baba Micheal, Baba Victor, Baba Damilola, iku tii ja'gbe mo ni koto pani, kekere Ekun ti kii se'gbe Ajakaja, Olodumare loni o ribe oko Ropo, oko Toyosi, Happy BORNDAY to my loyal brother from another Mama, Adeyemo Sunday Igboho Adeyemo Sunday Adeniyi Olojo ibi waa se opolopo odun l'aye oo, odoodun l'awo esegi, odoodun l'eegun njo, odoodun l'oro gb'ode, odoodun la o maa gb'ohun re si rere, akannamangbo kii p'odun je, odun o ni pa o je t'ayat'omo, ogbo ni t'orogbo, agba ni t'obi, ojo kan soso l'awo ntoro, tii fii lo egbeegberun odun l'aye, pelu alaafia ati idunnu, a gbo rakoro ni t'ahun, a gbo h'ewu ni t'agba agemo, iran alagemo kiiku lai f'opa rin, ogboato re o, moba o yo l'oni, anikun ni peregun nl'aso tie, anikun alafia fun o t'aya t'omo o, ogede agbaagba a lo gba gbogbo ire fun o loni, okete kii kawo lori d'oja koma ri tie se, waa ri tie se, onfa oka nii faa ounje fun oka, t'ere nii fa ounje fun ere, Ifa ni otororo omi Ido, womi loni ode Ijesha, orububitu loni Ijebu Ode, awon olomo nii gbeniga gege bi ade, awon ni won d'ifa fun Orunmila Baba Agbonmiregun l'ojo ti won ni awon yio bati Baba je, Baba ni iro nla ni, nitori daworo dawara omi kii denu apere koma koja, o di ewe o ni yerepe koma sai bawon ja, gbogbo eni bani awon yio ba tie je, ewe oni yerepe ko sai bawon ja t'ebi t'ara, bi oju bamo, ariwo a so nile ikun, oroorun kutukutu ariwo a so n'ile afe, ojumo kiimo ki patako alapata mon fi ara gba ogbe, osan gangan ni won nsan ekun, oworu kankan ni ewe ina joni, ki gbogbo awon ota re o maa sara won logbe iku ni, ekukeku kii dari jo je asin, kokoro ki kokoro kii dari jo je ikamudu, eyekeye kii dari jo je eye ega, at'Oso at'Aje aye won kii darijo ki won jeran alaileje, Adisa o d'Igbin eran alaileje l'oni, ota o ni di e l'owo, apa omode kii ka'gi ose, ajagbayi ni t'ara, owo kii lo enu aide, waa maa ri tie se, ejo ti adajo orun ba da, adajo aye kan kii tun daa mo, Oro Baba Ayomide, a jagba'yi ni t'Ara, bi afefe ba fe, igi oko nii gba'ku ree ku, o tidi peregun Igbodu Adisa, o tidi aboba Imole, ogboato e omo Adeyemo, awo lo nperi awo, mi o pe o fun iku o, moni koo gun l'emin ni l'oruko nla ti Olodumare ati Orunmila alagbawi aye!