07/06/2025
"IPARI ERÉ ÀRÍN" ERÉ ÀRÍN THE CONCLUSION part 1
Kí ọmọdé tàbí àwọn gende to pade nibi ere àrin, nwọn a ti wọ iho ti ko ju bi isun maji tabi mẹta, iho naa yíò si gbórò die. Niun iho yi ni nwọn yio tẹ ẹní pakiti si.
Ẹni pakiti ni iru ẹni ti awọn obinrin nhun ni Ipetu-ijesha; Ogotun ati Ọpọtọ li agbegbe Ekiti.
Bakanna ni nwọn o sí ti wa àrin bi mẹfa mẹfa tabi jiju bẹ lọ dani. Nwọn o fi "ẹmọ" tabi"amọ" do ori eyi ti o ba tobi ju ninu wọn.
Bi àrin enia ba ti wuwo to ni yio pa àrín ẹlòmíràn to. Bi o ba si ti pa to ni yio jẹ fun oluware to. Idi niyi ti a fi i yan olórí àrín wa fun eré àrín l'ojú agbo.
Enia mefa ni nta iru àrín yi lẹẹƙannaa. Bi nwọn ba pe merin nwọn o yọ"ìrin," eyi jasi pe nwọn o yọ alarin kẹrin naa kuro,a wa ku awọn mẹta.
Awọn mẹta ni yio si ta àrín wọn sinu ihò ti a tẹ ẹni si yi lẹƙannaa.
Awọn àrín yio si bẹrẹ si ijo ranin-ranin ninu ihò naa ti a npa ni"apẹ àrín" ni agbègbè miran.
Ìtumò rẹ si ni"ihò àrín".
Ẹnikẹni ti àrín tirẹ ba ta si'ta lati inu iho yi yio san arin miran fun ẹnití o ni arin ti o le e si'ta.
Ninu arin meji ti o kú eniti arin tirẹ ba tun ta si'ta yio san arin fun eniti o ni eyi ti o kú sinu ihò naa. Sugbon bi arin awọn mejeji ti o sẹku si'nu ihò ba tuka lẹkanna a jẹ ẹ'pe awọn meji naa"jẹ'gbọ" eyi ni pe nwọn ta"Ọmi'tabi nwọn ko pa ara wọn l'ayo.
Ọmi naa ni bi arin awọn mẹtẹta ba jade kuro ninu apẹ lẹẹkanna. Bi nwọn ba ti ta ọwọ kan ja, nwọn o tun bẹrẹ ọwọ keji ati ẹkẹta ati ẹkẹrin t**i nwọn o fi jẹ ara wọn l'arin tan patapata.
Ọnà keji ti a ngba ṣe eré arin yatọ pupọ si eyi ti a ṣe àlàyé rẹ tan yi.
Awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn gende paapaa maa nlọwọ ninu irufẹ eré arin bẹẹ. Lẹhin ti wọn ba ti ko arin jọ, ìrù arin kanna pẹlu eyi ti a ti gbọ àlàyé rẹ ni, nwọn a fa ìlà si ibi ti o te'ju pẹẹrẹ l'ọdẹdẹ wọn.
Ila ti nwọn yio fa kalẹ naa yio ni origun merin,yio si gun to opa mejila ni ooro ati opa mẹsan ni ìbá(ni'bi). Nwọn o tun fi opa ila kan t'ó gboro pin ojú agbo arin naa si meji ọgbọọgba.
Ere Arin si tun tesi waju